EROJA ewe aje tutu iyere diẹ iyere osun diẹ igbin nla kan
SISERE Ao boo igbin yen ao gesi meta, ao dasi Inu ape tuntun, ao lo ewe aje pelu iyere, ao fise igbin na lepo niyo. Ti obati fe jina ao wa te iyere osun na ni ejiogbe ao pe gbolohun re si,
OFORE:– Awaye masise 3x Awolu majiya 3x
Olaniyi 3x Awaye masise loruko tanpe iwo ifa, Awolu majiya loruko tanpe iwo esu odara. Olaniyi loruko tanpe eyin iyami aje. Eyin meteta ni mope kie de bayio, eni nitori ki mosen peyin tantan bayi, Moni nitori owo ni, eni tobaje Tori owoni odindi owo nla nla le ma gbewa fun emi– omo–, nitori odindi ni olugbo fi igbin tore fun olugbe, odindi owo nla nla ni ema gbewa fun emi– omo–, nitori odindi ni olugbe fi igbin tore fun ero oona, odindi owo nla nla le ma gbewa fun emi–omo–, nitori odindi ni ero oona fi igbin tore fun Orissa, odindi owo nla nla le ma gbewa fun emi– omo–, sebi lati kekere ni ewe aje ti gbegba aje ka omore lori, iyere osun ooo jowo Mase jeki iretemi osun Lona o, ki iremi masu lowo omode, lowo agba, lowo onile, lowo alejo.
Ao se adua si. ao dasi Lori ina, aoropo aoso aotun se adua si aoje. ỌDAJU
